Orin 001 - Olus'aguntan eni Re
Ago Re wonni ti li ewa to, Oluwa awon
Omo ogun OD. 84 : 1
- f Olus'aguntan eni Re
Fi are Re han wa,
'Wo fun wa n'ile adura
M'okan wa gbadura. - mf Fi ami ife Re han wa
So ireti wa ji
Se'ri'bukun Re s'ori wa
K'awa le ma yin O. - mf K'ife ati alafia
K'o ma gbe ile yi!
F'irora f'okan iponju
M'okan ailera le. - mf F'eti igbo, aya 'gbase,
Oju 'riran fun wa;
Tan imole Re lat'oke
K'a dagba l'or'ofe - mf K'a fi gbagbo gbo oro Re
K'a f'igbagbo bebe
Ati niwaju Oluwa
K'a se aroye wa.Amin.