Orin 003 - Ji okan mi, ba orun ji
Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD 103:2
- Ji okan mi, ba orun ji,
Mura si ise ojo Re,
Mase ilora, ji kutu,
K'o san 'gbese ebo oro. - Ro gbogb'ojo t'o fi sofo
Bere si rere 'se loni
Kiyesi 'rin re l'aye yi,
Ko si mura d'ojo nla ni. - K'oro re gbogbo j'otito,
K'okan re mo b'osan gangan
Mo p'Olorun nso ona re
O mo ero ikoko re. - Nipa 'mole ti nt'orun wa,
Tan 'mole na f'elomiran;
Jeki ogo Olorun 'han
Ninu ife at'orin 'yin. - Ji, gbonranu'wo okan mi,
Yan ipo re l'arin Angeli',
Awon ti won nkorin iyin
Ni gbogbo igba s'Oba wa. - Mo ji, mo ji, ogun orun,
Ki isin yin s'okan mi ji,
Ki nle lo ojo aye mi,
Fun Olorun mi bi ti yin.
Amin.