Orin 004 - Oluwa mi, mo njade lo
Ma rin niwaju mi, ki iwo ki o si pe. Gen. 17 : 1.
- Oluwa mi, mo njade lo
Lati se ise, oojo mi;
Iwo nikan l'emi o mo
Loro, lero, ati n'ise - Ise t'o yan mi l'anu Re
Jeki nle se tayo tayo
Ki nr'oju Re n'nu ise mi,
K'emi si le fi 'fe Re han. - Dabobo mi lowo 'danwo
K'o pa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aye yi
Ati gbogbo ifekufe. - cr Iwo t'oju Re r'okan mi
Ma wa l'ow'otun mi titi
Ki mna sise lo l'ase Re
Ki nfi 'se mi gbogbo fun O. - Je ki nreru Re t'o fuye,
Ki mna sora nigba gbogbo
Ki nma f'oju si nkan t'orun
Ki nsi mura d'ojo ogo. - Ohunkohun t'o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki n f'ayo sure ije mi,
Ki nba O rin titi d'orun.
Amin.