Orin 005 - Wa s'odo mi, Oluwa mi
Nigba wo ni Iwo o to mi wa! OD .101:2.
- Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni kutukutu owuro,
Mu k'ero rere so jade,
Lat'inu mi s'oke orun. - Wa s'odo mi, Oluwa mi,.
Ni wakati osan gangan;
Ki 'yonu ma ba se mi mo,
K'o si so osan mi d'orun. - Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Nigbati ale ba nle lo,
Bi okan mi ba nsako lo,
Mu pada, f'oju 're wo mi. - Wa s'odo mi, Oluwa mi,
L'oru, nigbati 'orun ko si,
Je ki okan aisim mi,
Simi le okan aya Re. - Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni gbogbo ojo aye mi,.
Nigbati emi mi ba pin
Ki nle n'ibugbe l'odo ReAmin.